Galatians 3:22-29

22 aṢùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. 24Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. 25Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́.

Ọmọ Ọlọ́run

26Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 27Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. 28 bKò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. 29Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

Copyright information for YorBMYO